9 Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù;ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá;bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n;àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ.
10 Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà,má sì fi olè jíjà yangàn;bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e.
11 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan,mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé,Ọlọrun ló ni agbára;
12 ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.Ò máa san ẹ̀san fún eniyangẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.