1 Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ,ọkàn rẹ ń fà mí;bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹṣe máa ń kóǹgbẹ omi.
2 Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ,mo ti rí agbára ati ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ,n óo máa yìn ọ́.
4 N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi;n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ.
5 Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù;n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.
6 Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru;