2 dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú;kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi.
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà;
4 wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn,láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì.
5 Wọ́n wonkoko mọ́ ète burúkú wọn;wọ́n ń gbìmọ̀ àtidẹ okùn sílẹ̀ níkọ̀kọ̀,wọ́n ń rò lọ́kàn wọn pé, “Ta ni yóo rí wa?
6 Ta ni yóo wá ẹ̀ṣẹ̀ wa rí?Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni a ti fi pète.”Áà, inú ọmọ eniyan jìn!
7 Ṣugbọn Ọlọrun yóo ta wọ́n lọ́fà;wọn óo fara gbọgbẹ́ lójijì.
8 Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ;gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn.