3 Ẹ sọ fún Ọlọrun pé,“Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ,agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ.
4 Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́;wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ,wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”
5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe,iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù.
6 Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀,àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò.Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe.
7 Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.
8 Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀;
9 ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀.