5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe,iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù.
6 Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀,àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò.Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe.
7 Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.
8 Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀;
9 ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀.
10 Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò;o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná.
11 O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.