7 Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.
8 Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀;
9 ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀.
10 Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò;o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná.
11 O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.
12 O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,a ti la iná ati omi kọjá;sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú.
13 N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ.