3 Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi,ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ,ojú mi sì di bàìbàì,níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi.
4 Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀,wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ.Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára.Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi,àwọn nǹkan tí n kò jíni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada.
5 Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ.
6 Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù,Ọlọrun Israẹli.
7 Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn,tí ìtìjú sì bò mí.
8 Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi.
9 Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.