10 Ọlọrun ni aláàbò mi,òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.
11 Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.
12 Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀;ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀,ó sì ti tọ́jú ọfà iná.
14 Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké.
15 Ó gbẹ́ kòtò,ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́.
16 Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀,àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí.