5 jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,kí ó tẹ̀ mí pa,kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
6 OLUWA, fi ibinu dìde!Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀.
7 Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá.
8 OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé;dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi.
9 Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀.
10 Ọlọrun ni aláàbò mi,òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.
11 Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.