9 Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀.
10 Ọlọrun ni aláàbò mi,òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.
11 Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.
12 Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀;ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀,ó sì ti tọ́jú ọfà iná.
14 Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké.
15 Ó gbẹ́ kòtò,ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́.