1 Ọlọrun, dákun, gbà mí,yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.
2 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mikí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,kí wọn sì tẹ́.
3 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì boàwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;kí wọn sì gba èrè ìtìjú.
4 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,kí inú wọn sì máa dùn,kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,“Ọlọrun tóbi!”