1 OLUWA, ìwọ ni mo sá di;má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!
2 Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!
3 Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.
4 Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,àwọn alaiṣootọ ati ìkà.
5 Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.
6 Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.