12 Ọlọrun, má jìnnà sí mi;yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!
13 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
14 Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.
15 N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.
16 N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.
17 Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,
18 Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.