15 N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.
16 N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.
17 Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,
18 Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.
19 Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?
20 O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.
21 O óo fi kún ọlá mi,o óo sì tún tù mí ninu.