7 Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8 Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.
9 Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.
10 Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,
11 wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹ lé e, ẹ mú un;nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”
12 Ọlọrun, má jìnnà sí mi;yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!
13 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.