19 Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.
20 Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.
21 Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,
22 mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.
23 Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.
25 Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.