4 Wọn kì í jẹ ìrora kankan,ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.
5 Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.
6 Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.
7 Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.
8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.
9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.
10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.