8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.
9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.
10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.
11 Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”
12 Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.
13 Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.
14 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.