1 Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli.
2 Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun.
4 Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ.
5 A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà.
6 Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira.
7 Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!Ta ló tó dúró níwájú rẹtí ibinu rẹ bá dé?