5 A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà.
6 Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira.
7 Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!Ta ló tó dúró níwájú rẹtí ibinu rẹ bá dé?
8 Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́;
9 nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀.
10 Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ;àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹyóo ṣe àjọ̀dún rẹ.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ,kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wáfún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù.