1 Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ;wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́;wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro.
2 Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹfún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ;wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹfún àwọn ẹranko ìgbẹ́.
3 Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu;kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin.
4 A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín.