6 Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́.
7 Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run;wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8 Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa;yára, kí o ṣàánú wa,nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa,nítorí iyì orúkọ rẹ;gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,nítorí orúkọ rẹ.
10 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé,“Níbo ni Ọlọrun wọn wà?”Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a palára àwọn orílẹ̀-èdè!
11 Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ,dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí.
12 OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́,san án fún wọn ní ìlọ́po meje,