4 Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?
5 O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.
6 O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó;
8 àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun,ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun.
9 OLUWA, Oluwa wa,orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!