1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA.
2 Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.
3 Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan.
4 Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ;ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ.