5 Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn,ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run.
6 Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀.
7 Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé;ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀.
8 Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀,ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀.
9 Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́;gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀.
10 Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.”
11 Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.