5 Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.
6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.
7 Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.
8 Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.
9 Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,o ju gbogbo ayé lọ,a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.
10 Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
11 Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.