9 Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,o ju gbogbo ayé lọ,a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.
10 Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
11 Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.
12 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.