1 OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.
2 OLUWA tóbi ní Sioni,ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
3 Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,mímọ́ ni OLUWA!
4 Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu.
5 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;mímọ́ ni OLUWA!