15 Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá,tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀,má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.
16 OLUWA ni ọba lae ati laelae.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo pòórá lórí ilẹ̀ rẹ.
17 OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára;o óo mú wọn lọ́kàn le,o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn
18 kí o lè ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbabaati àwọn ẹni tí à ń pọ́n lójú,kí ọmọ eniyan, erùpẹ̀ lásánlàsàn, má lè dẹ́rù bani mọ́.