1 N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí.
2 N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.
3 N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan.
4 Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan,