10 Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.
11 Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.
12 Lẹ́bàá orísun wọnyini àwọn ẹyẹ ń gbé,wọ́n sì ń kọrin lórí igi.
13 Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14 Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ,ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan,kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;
15 ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn,ati epo tí ń mú ojú eniyan dán,ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.
16 Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn,àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.