1 Ẹ yin OLUWA!Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeunnítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
2 Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán?Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn?
3 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́,àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo.
4 Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ńṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ.Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.