6 A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae,títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.
7 Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù,ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
8 Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á,níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9 Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka,òdodo rẹ̀ wà títí lae,yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá.
10 Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i.Yóo pa eyín keke, yóo pòórá,ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán.