1 Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada,ó dàbí àlá lójú wa.
2 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀,nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé,“OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!”
3 Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.
4 Dá ire wa pada, OLUWA,bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu.