3 Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.
4 Dá ire wa pada, OLUWA,bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu.
5 Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú,jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
6 Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún,yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀.