1 OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí.
2 O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde;o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré.
3 O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò;gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀.
4 Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.
5 O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi,ó ga jù, ojú mi kò tó o.
7 Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀?Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi?