3 O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò;gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀.
4 Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.
5 O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi,ó ga jù, ojú mi kò tó o.
7 Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀?Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi?
8 Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀!Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀.
9 Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá,kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí,