4 Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àwọn tí kì í ké pe OLUWA.
5 Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi,nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo.
6 Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú,ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀.
7 Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.