1 OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2 Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́.
3 OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.
4 Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.