1 OLUWA, gbọ́ adura mi;fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.
2 Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.
3 Ọ̀tá ti lé mi bá,ó ti lù mí bolẹ̀;ó jù mí sinu òkùnkùn,bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.
4 Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì;ọkàn mi sì pòrúúruù.
5 Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe,mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
6 Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.