1 Ẹ yin OLUWA!Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.
2 N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé;n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.
3 Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè;eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.
4 Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀,ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé.
5 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀.
6 Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,
7 ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀.