2 Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi;ìwọ nìkan ni orísun ire mi.”
3 Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí,wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn.
4 “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀:Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.”
5 OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn;ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀.
6 Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ;ogún rere ni ogún ti mo jẹ.
7 Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye;ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru.
8 Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo,nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀.