8 Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo,nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀.
9 Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn;ara sì rọ̀ mí.
10 Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú,bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́.
11 O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí;ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ,ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.