22 Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé,n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀.
23 Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀.
24 Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.
25 Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́,ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé;
26 mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́,ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ.
27 Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.
28 Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.