1 Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀,tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi,kí o sì ràn mí lọ́wọ́?
2 Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án,ṣugbọn o ò dáhùn;mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́.
3 Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́,o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́.
4 Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n.
5 Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.