4 Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n.
5 Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.
6 Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
7 Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;wọ́n sì ń mi orí pé,
8 “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!”
9 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú.
10 Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́;ìwọ ni Ọlọrun miláti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi.