1 OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!
2 Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!
3 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.
4 Mo ké pe OLUWA,ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.
5 Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.