4 Mo ké pe OLUWA,ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.
5 Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.
6 Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi kákò le bà mí lẹ́rù.
7 Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú.
8 OLUWA níí gbani,kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.