1 N óo yìn ọ́, OLUWA,nítorí pé o ti yọ mí jáde;o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
2 OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́,o sì wò mí sàn.
3 OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkúo sọ mí di ààyè láàrin àwọn tíwọ́n ti wọ inú kòtò.
4 Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.
5 Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀,ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀;eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́,ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀.
6 Nígbà tí ara rọ̀ mí,mo wí ninu ọkàn mi pé,kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae.
7 Nípa ojurere rẹ, OLUWA,o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá;ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi,ìdààmú dé bá mi.