8 Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.
9 Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́.
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun,kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.
11 Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ,má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi,kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró.
13 Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ,àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ.
14 Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun,ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi,n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ.